Oríkì Ọ̀rúnmìlà translated by Eny Tosyn

Ifá Olókun, A–sọ̀rọ̀–dayò, Ẹlẹ́rìí-ìpin, Ibìkejì Èdùmàrè.

The Diviner of the Sea, the one who makes affairs prosper, Witness to Creation, Second to the Creator.
Ọ̀rúnmìlà ni Baba wa o e, àwa kò ni Ọba méjì, Ifá tó Ọba o, Ọ̀rúnmìlà ni Baba wa, Ifá tó Ọba o.
Spirit of Destiny is our Father, we have no other King, Ifa is sufficient to be our king. Spirit of Destiny is our Father. Ifa is competent enough to be king.
Ká mọ̀ ọ́ ká là, Ká mọ̀ ọ́ ká má tètè kú, Amọ̀là Ifẹ̀ owòdáyé.
Whom to know is to be saved, Whom to know is to live a long life The Savior of Ife from the early days.
Ọkùnrin dúdú òkè Ìgètí, Olúwà mi àmọ̀– ìmọ̀–tán, Olúmmaàmi Òkítíbìrí.
The Black Man of Igeti Hill, the Chief who cannot be fully comprehended, The Chief Averter.
Tí npọjọ́ ikú dà, a kò mọ̀ ọ́ tán ìbá se, a bá mọ̀ ọ́ tán ìbá se.
The charger of the determined day of death, not to have full knowledge of you is to fail, to have full knowledge of you is to be successful.
Onílégangan–ajíkí, Àáyán–awo–inú– igbó, Amáiyégún
The first of the many houses that we praise, Chief diviner of the inner forest, powerful medicine of the earth.
Bara Petu, Baba kékeré Òké Ìgètí, Òrìsà tí ó fi gbogbo ayé fi ojú orórì sí pátápátá.
Father of Ipetu, the small man of Igeti, Spirit who has influence all over the World.
A bi ara ílu bí ajere, Òrìsà tí ngbé nkan òle gún, ‘Fágúnwà, ọkọ Ọ̀yẹ̀kú.
He, whose body can be shifted into many forms, the Spirit who gives strength to the weak, the husband of Oyeku.
Ọlọ́mú nlá, a bọ́’ni má rù, Baba Èsù Ọ̀dàrà , Òrìsà tí ngba’ni l’ọ́wọ́ ẹni tí ó ní ìkà nínú.
The big breasted man who feeds all people without loosing weight, the Father of the Divine Messenger of Transformation, the Spirit who saves us from destruction.
Baba akéré–fi–inú–se–ọgbọ́n, Òpìtàn Ifẹ̀, a tún’ni dá.
Father of small stature who is filled with wisdom, the Great Historian of Ife, he who makes recreation possible.
Òdùdù tíí du orí ìlémèrè kí orí ìlémèrè má ba à fọ́.
Savior of the child of Emere.
A tún orí ẹni tí kò sunwọ̀n se, fọ́nrán òwú kan soso, ajẹ́ ju oògùn.
He who changes bad luck into good luck, the Great Mystical Thread of Creation, he who manifests more effectively than charms.
Ará Ìwọ́nrán ní ibi tí ojú rere ti í mọ́ wá, Baba elépo púpọ̀ má jẹ àdín.
The original man from the place where dawn breaks, Father and owner of the palm oil that has no need to eat black oil.
A yọ́ tẹ́ẹ́rẹ́ gb’ára sán’lẹ̀ má fi ara pa, a s’ọ̀rọ̀ d’ayọ̀.
The young one who falls without injury, he who transforms worry into happiness.
Kí a mọ̀ ọ́ kí a là, Ọba Aládé Olódù Mẹ́rìndínlógún .
To know Him is to find salvation, King of the Sixteen Principles of Creation.
Ọ̀run ló mọ ẹni ti yíó là.
Only Heaven know who will be saved.
Onílé orí òkè tí nrí àfòpin ẹyẹ, s’ayé s’Ọ̀run Ìbíní.
Owner of a large house that is high enough to see the limit of the flight of the birds, dweller of earth and Heaven.
A jí pa ọjọ́ ikú dà, Baba mi Àgbọnnìrègùn, a tó í fi ara tì bí òkè.
He who wards off imminent death, my Father who we can lean on forever because He is as strong as a rock, He is the best person to spend time with.
Ọ̀gẹ̀gẹ̀ a gbé ayé gún, agírí Ilé Ìlọ́gbọ́n, àmọ̀ì–mọ̀ tán.
Light that stabilizes life, Chief of the town of Wisdom, He cannot be fully defined.
Ọmọ àdó baba tí í w’ẹ̀wù oògùn, Àjànà Ẹtà tí í mú orí Ẹkùn nsè’bo suuru suuru.
Father that wears a garment filled with charms, Ajana who sacrificed a lion’s head.
Òrìsà ọkọ Àjẹ́ Olójombán a rí apá ẹran sé ògùn, ase èyí tí ó sòro í se.
Husband of the Mothers, the Chief who conquers with the medicine of a goat, He who can perform the most difficult task.
Ẹ̀dú Ọlọ́jà orìbojo, Ọba a tún ọmọ dá bí ẹ̀wù, Òkunrin a tó eyín erin ní fífọn.
Most respected Black King, King who creates without effort, the powerful man who creates music on the tusk of an elephant.
Ikọ̀ Àjàláiyé ikọ̀ Àjàlọ́run.
Chief Messenger, the link between the King of the Earth and the King of the Realm of the Ancestors.
Òkítíbìrí, a–pa–ọjọ́–ikú–dà.
The Great Changer who alters the time of death.
Iríjú Olódùmarè.
The prime minister of the Creator.
Alátunse aiyé.
The one who whose function it is to set the world right.
Ikúforíjì.
The Being whom Death honours.
Ọba Ọlọ́fà asùn l’ọ́lá.
The ruler who draws blessings and prosperity after him and who sleeps in the midst of honours.
Ẹ̀ríntunde .
Laughing comes back to the world from the Realm of the Ancestors.
Ọwá.
Being who fills humanity with joy.
Olùbẹ̀san Olù–li–ibi–ẹ̀san.
The Chief Avenger of Wrongs.
Ẹ̀là ọmọ Òyígíyigì Ọta Omi.
Child of a very hard Stone that is not affected by a cold stream of water.
Ẹ̀là ọmọ Òyígíyigì Ọta Àìkú.
Child of a mighty immovable rock that shall never die.
Ọ̀tọ̀tọ̀–Ènìyàn.
The Perfect One.
Olúwa mi agírí–ìlọ́gbọ́n.
The Chief of Perfect Wisdom.
Ọmọ ti abi lòkè’tasẹ̀.
The child born on the hill of Itase.
Ọmọ ejò méjì.
Child of two serpents.
Akéré f’inú Sọgbọ́n.
Small person with a mind full of wisdom.
A kọ́ni–lọ́ràn–bí ìyekan–ẹni.
He who gives one wise and brotherly counsel like ones relatives.
Òkúkurú Òkè Ìgètí.
The small man of Igeti Hill.
Bara Àgbọnnìrègùn.
Chief of the sacred coconut palm.
Afèdèfẹyọ̀.
Speaker of all languages.
Gbólájókó.
He who sits in honour.
Olúwa mi àmòimọ̀tán.
King who knows all.
Ikú dúdú àtẹ́wọ́, Ọ̀rọ̀ a je’po má pọ̀n-ọ́n , Ọ̀rọ̀ a bá ikú j’ìgbò.
Black death of the palm, the Mystic who eats lots of palm oil and does not turn red, the Mystic who wrestles with death.
Ọ̀run ló mọ ẹni tí yíó là.
Only Heaven knows who will be saved.
A–ṣe ayé–ṣe ọ̀run.
One who lives on earth and lives in heaven.
Dùndúnké, obìnrin o– fìdí–han–ni–káso.
The robust, virile one who does not refuse a woman’s advances.
Ẹlẹ́rìí ìpín, ajẹ́–ju–ògùn.
One who is the witness of all destiny, one who is more effective than medicine.
Òrúnmilà! Ifá Olókun, Aṣọ̀rọ̀dayọ̀.
Spirit of Destiny, the owner of the sea, who turns misfortune into joy.
Olóòrérè–Àìkú, jẹ́– jòògùn.
One who saves people from death, one more effective than medicine.
Ìwọ laláwòyè o.
It’s you who can give life to people.
Bá mi wo ọmọ tèmi yè o.
Spirit who gives life to my children.
Ají–pa–ọjọ́–ikú–dà.
One who wakes up and changes the day of death.

Comments

Popular posts from this blog

“The Àjé

Yoruba

Yoruba Value System